Yoruba Hymn: Onigbagbọ ẹ bu s’ ayọ – All ye Christians burst into joy
Hymn 164: Onigbagbọ, ẹ bu s’ ayọ – All ye Christians burst into joy
Bible Reference:
Psalms 118:24 NKJV – This is the day the Lord has made; We will rejoice and be glad in it.
Orin dafidi 118:24 – Eyi li ọjọ ti Oluwa da: awa o ma yọ̀, inu wa yio si ma dùn ninu rẹ̀.
Onigbagbọ ẹ bu s’ ayọ
VERSE 1
Onigbagbọ, ẹ bu s’ ayọ, Ọjọ nla l’ eyi fun wa; Ẹ gbọ bi awọn Angẹli Ti nf’ ogo fun Ọlọrun: Alafia, Alafia Ni fun gbogbo eniyan.
VERSE 2
Ki gbogbo aiye ho f’ ayọ, K’ a f’ ogo fun Ọlọrun, Ọmọ bibi Rẹ l’ o fun wa T’ a bi ninu Wundia: Ẹn’ Iyanu, Ẹn’ Iyanu Ni Ọmọ t’ a bi loni
VERSE 3
Ninu gbogbo rudurudu, On ibi t’ o kun aiye, Ninu idamu nla ẹsẹ L’ Ọm’ Ọlọrun wa gba wa: Olugbimọ, Olugbimọ, Alade Alafia
VERSE 4
Ọlọrun Olodumare L’ a bi, bi ọmọ titun: Baba ! Eni aiyeraiye L’ o di alakoso wa: Ẹ bu s’ ayọ, Ẹ bu s’ ayọ, Ọmọ Dafidi jọba.
VERSE 5
O wa gba wa lọwọ ẹsẹ, O wa d’ onigbọwọ wa Lati fọ itẹgun Esu A ṣe ni Ọba Ogo: Ẹ ku ayọ, Ẹ ku ayọ, A gba wa lọwọ iku. Amin.
All ye Christians burst into joy
VERSE 1
All ye Christians burst into joy, Great day this hath been to us; Hark as the host of Angels sing Glorious praises unto God. O! Perfect peace, O! perfect peace Be unto all ye mankind
VERSE 2
Let all who dwell on earth rejoice, And give glory unto God. His only Son He hath offered Begotten of a virgin. Wonderful Being, Wonderful Being Is He that is born today
VERSE 3
Through all the temptest and furmoil And the wickedness on earth In great tribulations of sin Son of God us to redeem. O! Counsellor, O! Counsellor: Oh The Royal Prince of peace
VERSE 4
Almighty, Omnipotent God Like a babe is born today: Everlasting Father and Being Our Royal Ruler He is. Burst into joy, burst into joy The Son of David reigneth
VERSE 5
From sin He hath come to save us, Our Mediating help He is Stronghold of satan to pull down Our King of Glory he is: Felicitate, Felicitate From the pang of death we’re saved