Yoruba Hymn: Gba aiye mi Oluwa – Take my life and let it be

Yoruba Hymn: Gba aiye mi Oluwa  – Take my life and let it be

Hymn 735: Gba aiye mi Oluwa  – Take my life and let it be

Bible Reference: 

Romans 12:1b NKJV – …that you present your bodies a living sacrifice, holy, acceptable to God, which is your reasonable service.

Rom. 12: 1b – Ki ẹnyin ki o fi ara nyin fun Ọlọrun li ẹbọ ãye, mimọ́, itẹwọgbà, eyi ni iṣẹ-isìn nyin ti o tọ̀na.

Gba aiye mi, Oluwa

VERSE 1

Gba aiye mi, Oluwa,
Mo ya si mimọ fun Ọ;
Gba gbogbo akoko mi,
Ki wọn kun fun iyin Rẹ.

VERSE 2

Gba ọwọ mi, k’O si jẹ
Ki nma lo fun ìfẹ Rẹ.
Gba ẹsẹ mi, k’ O si jẹ
Ki wọn ma sare fun Ọ.

VERSE 3

Gba ohun mi, je ki nma
Kọrin f’ Ọba mi titi;
Gba ete mi, jẹ ti wọn
Ma jisẹ fun Ọ titi;

VERSE 4

Gba wura, fadaka mi,
Okan nki o da duro;
Gba ọgbọn mi, ko sil lo,
Gẹgẹ bi O ba ti fẹ.

VERSE 5

Gba ‘fẹ mi, fi ṣe Tirẹ;
Ki o tun jẹ t'emi mọ;
Gb’ ọkan mi, Tirẹ n’iṣe
Ma gunwa nibẹ titi.

VERSE 6

Gba ‘fẹran mi, Oluwa,
Mo fi gbogbo rẹ fun Ọ,
Gb’ emi papa; lat’ oni
Ki ‘m’ jẹ Tirẹ titi lai. Amin.

Take my life, and let it be

VERSE 1

Take my life, and let it be
Consecrated, Lord, to Thee;
Take my moments and my days,
Let them flow in ceaseless praise.

VERSE 2

Take my hands, and let them move
At the impulse of Thy love;
Take my feet and let them be
Swift and beautiful for Thee.

VERSE 3

Take my voice, and let me sing
Always, only, for my King;
Take my lips, and let them be
Filled with messages from Thee

VERSE 4

Take my silver and my gold;
Not a mite would I withhold;
Take my intellect, and use
Every power as Thou shalt choose.

VERSE 5

Take my will, and make it Thine;
It shall be no longer mine.
Take my heart; it is Thine own;
It shall be Thy royal throne.

VERSE 6

Take my love; my Lord, I pour
At Thy feet its treasure-store.
Take myself, and I will be
Ever, only, all for Thee. Amen

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *