Yoruba Hymn: Ọba aiku airi, orísun ọgbọn – Immortal, invisible, God only wise

Hymn 99 – CHRIST APOSTOLIC CHURCH HYMNAL

 

Bible Reference: 1 Tim. 1:17 Njẹ fun Ọba aiyeraiye, aidibajẹ, airi, Ọlọrun kanṣoṣo, ni ọlá ati ogo wà fun lai ati lailai. Amin

 

Now to the King eternal, immortal, invisible, to God who alone is wise, be honor and glory forever and ever. Amen.

I Timothy 1:17 NKJV

 

Ọba aiku airi, orísun ọgbọn

 

Ọba aiku airi, orísun ọgbọn

To wa n’nu imọlẹ toju kole wo,

Olubukun julọ, Ologo julọ

Alagbara, Olusẹgun, ‘Wo la yin.

 

Laisimi, laiduro, ni idakẹjẹ,

O njọba lọ, O ko sí ṣe alaini; 

Gíga ni idajọ Rẹ bi oke nla,

Ikuku Rẹ b’Isun ire at’ifẹ

 

O ntẹ gbogbo ẹda alaye lọrùn,

Nipa ìmísí Rẹ wọn gbé ìgbé wọn

A ndagba, a ngbilẹ bi ewe igi,

A sì nro; ṣugbọn bakanna l’Ọlọrun.

 

Bàbá nla Ologo imọlẹ pipe

Awọn angẹli Rẹ wolẹ l’ẹsẹ Rẹ!

Iyin wa la mu wa, jọ ran wa lọwọ,

K’a le r’ogo imọlẹ to yi Ọ ka.

 

                                      Amin. 

 

Immortal, invisible, God only wise

 

Immortal, invisible, God only wise,

In light inaccessible hid from our eyes,

Most blessed, most glorious, the Ancient of Days,

Almighty, victorious, Thy great name we praise.

 

Unresting, unhasting, and silent as light,

Nor wanting, nor wasting, Thou rulest in might;

Thy justice like mountains high soaring above

Thy clouds which are fountains of goodness and love.

 

To all life Thou givest, to both great and small;

In all life Thou livest, the true life of all;

We blossom and flourish as leaves on the tree,

And wither and perish, but nought changeth Thee.

 

Great Father of Glory, pure Father of Light

Thine angels adore Thee, all veiling their sight;

All laud we would render, O help us to see:

’Tis only the splendor of light hideth Thee.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *