Yoruba Hymn: Oluwa ran mi ni’se Aleluya- I have a message from the Lord Hallelujah
Oluwa ran mi ni’se Aleluya
Hymn no.208 of the Christ Apostolic Church Hymn Book
Bible Reference: And the Lord said unto Moses, Make thee a fiery serpent, and set it upon a pole: and it shall come to pass, that every one that is bitten, when he looketh upon it, shall live.
Numbers 21:8 KJV
Numeri 21:8 OLUWA si wi fun Mose pe, Rọ ejò amubina kan, ki o si fi i sori ọpá-gigùn kan: yio si ṣe, olukuluku ẹniti ejò ba bùṣan, nigbati o ba wò o, yio yè
- Oluwa ran mi ni’se, Aleluya!
Iwọ ni un o jẹ iṣẹ na fún;
A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya!
P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye.
Wo k’o ye, Arakurin
Wo Jesu ki í sí ye
A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya!
P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye.
- A rán mi ni’se ayọ, Aleluya!
Un ọ j’iṣẹ na fún ọ ọrẹ mi;
Iṣẹ lat’oke wa ni Aleluyah!
Jésù sọ, mo mọ pé otọ ni.
Wo k’o ye, Arakurin
Wo Jesu ki í sí ye
A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya!
P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye.
- A n’ọwọ iye sí ọ, Aleluya!
Ao fi’ye ailopin fún ọ;
T’o ba wo Jesu nikan, Aleluya!
Wòó, On nìkan l’o le gbala.
Wo k’o ye, Arakurin
Wo Jesu ki í sí ye
A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya!
P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye.
I have a message from the Lord Hallelujah
Verse 1
I’ve a message from the Lord, Hallelujah!
The message unto you I’ll give;
‘Tis recorded in His Word, Hallelujah!
It is only that you ” look and live”
Chorus
`Look and live,` my brother, live!
Look to Jesus now and live;
‘Tis recorded in His Word, Hallelujah!
It is only that you `look and live!`
Verse 2
I’ve a message full of love, Hallelujah!
A message, O my friend for you;
‘Tis a message from above, Hallelujah!
Jesus said it and I know ’tis true!
Chorus
`Look and live,` my brother, live!
Look to Jesus now and live;
‘Tis recorded in His Word, Hallelujah!
It is only that you `look and live!`
Verse 3
Life is offered unto thee, Hallelujah!
Eternal life thy soul shall have,
If you’ll only look to Him, Hallelujah!
Look to Jesus who alone can save.
Chorus
`Look and live,` my brother, live!
Look to Jesus now and live;
‘Tis recorded in His Word, Hallelujah!
It is only that you `look and live!`
Author: William A. Ogden (1887)