Yoruba Hymn: Anu Rẹ, Oluwa l’awa ntọrọ
Hymn: Anu Rẹ, Oluwa l’awa ntọrọ
Culled from the First African Church Mission Hymnal
Anu Rẹ, Oluwa l’awa ntọrọ,
K’ O rọ ‘jo rẹ lè wà,
Ẹiyẹ ti nfo, at’era ti nrin n’ lẹ,
Ri wọn lọpọlọpọ,
Refrain
Anu, anu, anu Rẹ Baba wa ọrún,
L’awa ntọrọ
Ẹiyẹ ti nfo, at’ era ti nrin n’ lẹ,
Ri wọn lọpọlọpọ
Orun l’ọsan, nipa anu Rẹ ni,
At’osupa l’oru
Igba ojo, ati igba ẹrun,
L’ọwọ Rẹ ni wọn wà.
Refrain
‘Gbati eṣu at’ ẹsẹ ndọdẹ wa,
Ikọlu wọn ṣọro,
L’ogo asan, arankan, lil’ aiya,
Oluwa, gba wa la.
Refrain
Dáfídì kólé gbagbe anu Rẹ̀,
Niwaju Golayat,
Danieli ni arin kìnìún,
Tal’ o ha ṣ’ abo Rẹ?
Refrain
Iru anu wọnyi l’awa ntọrọ,
S’ alabojuto wa,
Larin ọta jẹ ki awa ma gba
Fún iyi, Ogo Rẹ
Refrain
Amin.