Yoruba Hymn: Ma koja mi Olugbala – Pass me not O gentle Savior

Yoruba Hymn: Ma koja mi Olugbala – Pass me not O gentle Savior

Hymn: Ma koja mi Olugbala – Pass me not O gentle Savior

Bible Reference: 

Joel 2:32  NKJV – And it shall come to pass That whoever calls on the name of the LORD

Shall be saved. For in Mount Zion and in Jerusalem there shall be deliverance,

As the LORD has said, Among the remnant whom the LORD calls. 

Joeli 2:32  Yio si ṣe ẹnikẹni ti o ba ke pè orukọ Oluwa li a o gbàla: nitori li oke Sioni ati ni Jerusalemu ni igbàla yio gbe wà, bi Oluwa ti wi, ati ninu awọn iyokù ti Oluwa yio pè

Ma koja mi, Olugbala

Ma kọja mi, Olugbala,
Gbọ adura mi;
’Gbat’ Iwọ ba np’ elomiran,
Mase kọja mi!
Jesu! Jesu! Gbọ adura mi!
Gbat’ Iwọ ba np’ elomiran,
Mase kọja mi.
N’ itẹ-anu, jẹ k’ emi ri
Itura didun;
Tẹduntẹdun ni mo wolẹ,
Jọ ran mi lọwọ.
Jesu! Jesu! &c.
N’ igbẹkẹle itoye Rẹ,
L’ em’ o w’ oju Rẹ;
Wo ’banujé ọkan mi san,
F’ ìfẹ Rẹ gba mi.
Jesu ! Jesu ! &c.
’Wọ orisun itunu mi,
Ju ’ye fun mi lọ;
Tani mo ni laiye lọrùn,
Bikòṣe Iwọ?
Jesu ! Jesu ! &c. Amin.


Pass me not, O gentle Savior

Pass me not, O gentle Savior,
Hear my humble cry;
While on others Thou art calling,
Do not pass me by.
Saviour, Saviour, etc.
Hear my humble cry;
While on others Thou art calling,
Do not pass me by.
Let me at Thy throne of mercy
Find a sweet relief;
Kneeling there in deep contrition,
Help my unbelief.
Saviour, Saviour, etc.
Trusting only in Thy merit,
Would I seek Thy face;
Heal my wounded, broken spirit,
Save me by Thy grace.
Saviour, Saviour, etc.
Thou the spring of all my comfort,
More than life to me;
Whom have I on earth beside Thee?
Whom in heaven but Thee?
Saviour, Saviour, etc. Amen.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *