Yoruba Hymn: Jesu Yè Titi Aye – Jesus Lives! Thy Terrors Now

Yoruba Hymn: Jesu Yè Titi Aye – Jesus Lives! Thy Terrors Now

Hymn: Jesu Yè Titi Aye –  Jesus Lives! Thy Terrors Now

Bible Reference: 

Revelation 1:18 NLT: I am the living one. I died, but look—I am alive forever and ever! And I hold the keys of death and the grave. 

Ifihan 1:18 YBCV Emi li ẹniti o mbẹ lãye, ti o si ti kú; si kiyesi i, emi si mbẹ lãye si i titi lai, Amin; mo si ní kọkọrọ ikú ati ti ipo-oku.

Jesu Yè Titi Aye

Ẹsẹ 1

Jesu yè titi aye,
Ẹru iku ko bà ni mọ;
Jesu yè: nitorina
Isa oku ko n’ ipa mọ.
Alleluya.

Ẹsẹ 2

Jesu yè: lat’ oni lọ,
Iku jẹ ọna si iye:
Eyi y’ o jẹ ‘tunu wa,
‘Gbat’ akoko ikú ba de.
Alleluya.

Ẹsẹ 3

Jesu yè: fun wa l’ O kú,
Njẹ Tirẹ ni a o mã ṣe;
A o f’ ọkàn funfun sin,
A o f’ ogo f’ Olugbala.
Alleluya.

Ẹsẹ 4

Jesu yè: eyi daju,
Iku at’ ipa okunkun
Ki y’ o le yà ni kuro
Ninu ifẹ nla ti Jesu.
Alleluya.

Ẹsẹ 5

Jesu yè: gbogbo ‘jọba
L’ Ọrun, li aye di Tirẹ;
Ẹ jẹ ki a mã tẹle E,
Ki a le jọba pẹlu Rẹ.
Alleluya.

Jesus Lives! Thy Terrors Now

Verse 1

Jesus lives! thy terrors now
Can, O death, no more appal us;
Jesus lives! by this we know
Thou, O grave, canst not enthral us.
Hallelujah!

Verse 2

Jesus lives! henceforth is death
Entrance-gate of life immortal;
This shall calm our trembling breath,
When we pass its gloomy portal.
Hallelujah!

Verse 3

Jesus lives! for us He died;
Hence may we, to Jesus living,
Pure in heart and act abide,
Praise to Him and glory giving.
Hallelujah!

Verse 4

Jesus lives! our hearts know well
Nought from us His love shall sever;
Life, nor death, nor powers of hell
Part us now from Christ for ever.
Hallelujah!

Verse 5

Jesus lives! to Him the throne
High o'er heaven and earth is given;
We may go where He is gone,
Live and reign with Him in heaven.
Hallelujah!

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *