Yoruba Hymn: Wa s’ọdọ mi, Oluwa mi – Come to me, Lord, when first I wake
Hymn: Wa s’ọdọ mi, Oluwa mi – Come to me, Lord, when first I wake
Bible Reference: Psalms 101:2 (NKJV) I will behave wisely in a perfect way.
Oh, when will You come to me?I will walk within my house with a perfect heart.
Orin Dafidi 101:2 – Emi o ma rìn ìrin mi pẹlu ọgbọ́n li ọ̀na pipé. Nigbawo ni iwọ o tọ̀ mi wá! emi o ma rìn ninu ile mi pẹlu aiya pipé.
Wa s’ọdọ mi, Oluwa mi (CAC Hymn no. 5)
Wa s’ọdọ mi, Oluwa mi, Ni kutukutu owurọ; Mu k’ ero rere sọ jade, Lat’ inu mi soke ọrun.
Wa s’ọdọ mi Oluwa mi, Ni wakati ọsan gangan; Ki ’yọnu ma ba ṣẹ mi mọ K'o si sọ ọsán mi d’ oru.
Wa s’ọdọ mi Oluwa mi, Nigbati alẹ ba nlẹ lọ; Bi ọkan mi ba nsako lọ, Mu pada; f’oju ’rẹ wo mi.
Wa s’ọdọ mi Oluwa mi, L'oru, nigbat'ọru kò sí, Jẹ ki ọkan aisimi mi Simi le ọkan aya Rẹ.
Wa s’ọdọ mi Oluwa mi, Ni gbogbo ojo aiye mi; Nigbati ẹmi mi ba pin, Kin le n’ ibugbe lọdọ Re. Amin.
Come to me, Lord, when first I wake
Come to me, Lord, when first I wake, As the faint lights of morning break; Bid purest thoughts within me rise, Like crystal dew-drops to the skies.
Come to me in the sultry noon, Or earth's low communings will soon Of Thy dear face eclipse the light, And change my fairest day to night.
Come to me in the evening shade, And, if my heart from Thee hath stray’d, Oh bring it back, and from afar Smile on me like Thine evening star.
Come to me in the midnight hour, When sleep withholds its balmy power; Let my lone spirit find her rest, Like John, upon my Saviour's breast.
Come to me through life's varied way, And when its pulses cease to play, Then, saviour, bid me come to Thee, That where Thou art, Thy child may be. Amen.