Yoruba Hymn: Ọlọrun igbala wa- O God of our salvation

Yoruba Hymn: Ọlọrun igbala wa- O God of our salvation

Hymn: Ọlọrun igbala wa O God of our salvation

Bible Reference: 

Psalms 79:13: So we, Your people and sheep of Your pasture, Will give You thanks forever; We will show forth Your praise to all generations. 

O. Daf 79:13  –  Nígbà náà, àwa eniyan rẹ, àní, àwa agbo aguntan pápá rẹ, yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae; a óo sì máa sọ̀rọ̀ ìyìn rẹ láti ìran dé ìran.

Ọlọrun igbala wa

Ẹsẹ 1

Ọlọrun igbala wa,
Ẹmi at’ iye wa,
Ilera at’ abo wa
At’ alafia wa;
Awa ọmọ Rẹ duro
Lati fi ‘yin fun Ọ,
Fun ẹbun nla t’ O fun wa
Ninu Kristi Jesu.

Ẹsẹ 2

Ọkàn wa kun fun ọpẹ,
Fun ‘tọju ‘gbagbogbo
Lori awọn ọmọ Rẹ
Ni gbogbo agbaye;
Awa mbẹ Ọ jẹ k’ awa
Le duro n’ nu ‘fẹ Rẹ,
Ki ‘mọlẹ wa le ma tàn
Yi gbogbo aye ka.

Ẹsẹ 3

Ògo f’ Ọlọrun Baba,
At’ Ọlọrun Ọmọ,
Pẹlu Ọlọrun Ẹmi,
Mẹtalọkan laelae,
Jọọ gba orin iyin wa,
Ati adura wa,
Fun ẹbun nla t’ O fun wa
Ninu Kristi Jesu.

O God of our salvation

Verse 1

O God of our salvation
Our Spirit soul and life
Our health, shield and defender
Our everlasting peace
We Thy children humbly stand
To glorify Thy name
For the great gift you bestow
Through Jesus Christ Thy Son.

Verse 2

Our hearts are filled with praises
For all Thy ceaseless care
On all of Thy dear children
Scattered all o'er the world
We implore Thee to help us
Continue in Thy will
And that our light may so shine
Upon the whole wide world.

Verse 3

Glory to God the Father
Glory to God the Son
To Holy Ghost give glory
Ever blessed Three-in-One
Accept our songs of praises
Also the prayer we bring
For the great gift you bestow
Through Jesus Christ Thy Son.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *