Yoruba Hymn: Olori Ijọ T’ Ọrun – Head Of The Church Triumphant

Yoruba Hymn: Olori Ijọ T’ Ọrun – Head Of The Church Triumphant

CAC Hymn: Hymn 81: Olori Ijọ t’ ọrun – Head of the Church triumphant

Bible Reference: 

Acts 14:22 NKJV – strengthening the souls of the disciples, exhorting them to continue in the faith, and saying, “We must through many tribulations enter the kingdom of God.”

Iṣe Apo 14:22 –  Nwọn nmu awọn ọmọ-ẹhin li ọkàn le, nwọn ngbà wọn niyanju lati duro ni igbagbọ́, ati pe ninu ipọnju pipọ li awa o fi wọ̀ ijọba Ọlọrun.

Olori Ijọ t’ ọrun

Olori Ijo t’ ọrun,
L’ ayọ l’ a wolẹ fun Ọ;
K’ O to de, ìjọ t’ aiye,
Y’ o ma kọrin bi t’ ọrun.
A gbe ọkan wa s’ oke,
Ni ‘reti t’ o ni ‘bukun;
Awa kigbe, awa f’ iyin
F’ Ọlọrun igbala wa.

‘Gbat’ a wa ninu pọnju,
T’ a nkọja ninu ina,
Orin ifẹ l’ awa o kọ,
Ti o nmu wa sunmọ Ọ;
Awa sape, a si yọ,
Ninu ojurere Rẹ;
Ìfẹ t’ o sọ wa di Tirẹ,
Y’o ṣe wa ni Tirẹ lai.
Iwọ mu awọn enia Rẹ 
Kọja iṣan idanwo:
A ki o bẹru wahala,
T’ori O wa nitosi:
Aiye, ẹsẹ, at’ Èsù,
Kọjuja si wa lasan
L’ agbara Rẹ, a o ṣẹgun,
A o si kọ orin Mose.
Awa f’ ìgbàgbọ r’ ogo,
T’ o tun nfẹ fi wa si;
A kẹgàn aiye tori
Ere nla iwaju wa.
Bi O ba si ka wa ye,
Awa pẹlu Stefen t’ o sun,
Y’o ri Ọ bi o ti duro,
Lati pe wa lọ s’ ọrun. Amin

Head of the Church triumphant

Head of the Church triumphant,
We joyfully adore Thee;
Till Thou appear, Thy members here
Shall sing like those in glory.
We lift our hearts and voices,
With blessed anticipation,
And cry aloud, and give to God
The praise of our salvation.
While in affliction's furnace,
And passing through the fire,
Thy love we praise in grateful lays,
Which ever brings us nigher:
We clap our hands, exulting
In Thine almighty favour:
The love divine, that made us Thine,
Shall keep us Thine for ever.
Thou dost conduct Thy people
Through torrents of temptation:
Nor will we fear, while Thou art near,
The fire of tribulation;
The world, with sin and Satan,
In vain our march opposes,
By Thee we shall break through them all,
And sing the song of Moses.
By faith we see the glory
To which Thou shalt restore us,
The world despise, for that high prize
Which Thou hast set before us;
And, if Thou count us worthy,
We each, with dying Stephen,
Shall see Thee stand at God's right hand,
To call us up to Heaven. Amen

Author: Charles Wesley

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *