Yoruba Hymn: Ọkan Mi Nyọ Ninu Oluwa – My Soul Is So Happy In Jesus

Yoruba Hymn: Ọkan Mi Nyọ Ninu Oluwa – My Soul Is So Happy In Jesus

Hymn 259: Christ Apostolic Church Hymnal

Yoruba Version of  My soul is so happy in Jesus hymn – Ọkan Mi Nyọ Ninu Oluwa

 

Scripture Reference:

Filipi 4:4 – Ẹ mã yọ̀ ninu Oluwa ni gba gbogbo: mo si tún wi, Ẹ mã yọ̀.

Philippians 4:4 NKJV – Rejoice in the Lord always. Again I will say, rejoice!

 

Ọkan Mi Nyọ Ninu Oluwa

 

Ọkan mi nyọ ninu Oluwa

“Tori O jẹ iye fún mi,

Ohun Rẹ dun púpọ̀ láti gbọ

Adun ni lati r’iju Rẹ,

Emi nyọ ninu Rẹ,

Emi nyọ ninu Rẹ,

Gba gbogbo lo fi ayọ̀ kun ọkan mi

“Tori emi nyọ ninu Rẹ

 

O ti pẹ t’O ti nwa mi kiri,

‘Gbati mo rin jina s’agbo,

O gbe mi wa sile l’apa Rẹ

Níbití papa tutu wa,

Emi nyọ ninu Rẹ,

Emi nyọ ninu Rẹ,

Gba gbogbo lo fi ayọ̀ kun ọkan mi

“Tori emi nyọ ninu Rẹ

 

Ire at’anu Rẹ yi mi ka,

Ore-ọfẹ Rẹ nṣàn bi odo,

Ẹmi Rẹ ntọ, o sí nẹe ‘tutu,

O mbá lọ sí ‘bikibi,

Emi nyọ ninu Rẹ,

Emi nyọ ninu Rẹ,

Gba gbogbo lo fi ayọ̀ kun ọkan mi

“Tori emi nyọ ninu Rẹ

 

Èmí y’o dàbí Rẹ ni jọ kan,

Un ọ s’ẹru wuwo mi kalẹ,

Titi di ‘gbana un o ṣ’olotọ,

Ni ṣiṣẹ ọṣọ f’ada Rẹ

Emi nyọ ninu Rẹ,

Emi nyọ ninu Rẹ,

Gba gbogbo lo fi ayọ̀ kun ọkan mi

“Tori emi nyọ ninu Rẹ. Amin

 

My Soul Is So Happy In Jesus

 

My soul is so happy in Jesus,

For He is so precious to me;

His voice it is music to hear it,

His face it is heaven to see. 

 

Refrain:

I am happy in Him,

I am happy in Him;

My soul with delight

He fills day and night,

For I am happy in Him. 

 

He sought me so long ere I knew Him,

When wand’ring afar from the fold;

Safe home in His arms He hath bro’t me,

To where there are pleasures untold.

 

[Refrain]

 

His love and His mercy surround me,

His grace like a river doth flow;

His Spirit, to guide and to comfort,

Is with me wherever I go.

 

 [Refrain]

 

They say I shall some day be like Him,

My cross and my burden lay down;

Till then I will ever be faithful,

In gathering gems for His crown. 

 

[Refrain]

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *