Yoruba Hymn: O Dara, F’ ọkan Mi – It Is Well, with My Soul
O Dara, F’ ọkan Mi – It Is Well, with My Soul
Bible Reference:
2 Kings 4:26 – Please run now to meet her, and say to her, ‘Is it well with you? Is it well with your husband? Is it well with the child?’ ”And she answered, “It is well.”
[2 Ọba 4:26 YCB – Sáré lọ pàdé rẹ̀ kí o sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ‘Ṣé o wà dáradára? Ṣé ọkọ rẹ wà dáradára? Ṣé ọmọ rẹ wà dáradára?’ ” Ó wí pé, “Gbogbo nǹkan wà dáradára.”
Ẹsẹ 1
‘Gbat’ ayọ bi odo ṣiṣan de b’ọkan mi,
‘Gba ‘banujẹ tẹri mi ba,
Ey’ o wu k’o jẹ, ‘Wọ nkọ mi ki nwipe,
O dara, o dara, f’ọkan mi,
O dara . . . . . . f’ ọkan mi,
O dara, o dara, f’ ọkan mi.
Ẹsẹ 2
B’ Eṣu tilẹ nhalẹ, ti ‘danwo nyi lu mi,
Idakọro mi ko le yẹ;
‘Tori Jesu ti mọ gbogb’ ailera mi,
Ẹjẹ Rẹ nṣ’ etutu f’ ọkan mi.
Ẹsẹ 3
Ọjọ nã ba yara de ti ngo r’ oju Rẹ,
Ti ‘ṣudẹdẹ y’o rekọja,
Ipe y’o si dun, Oluwa mi y’o de,
Nigbana y’o dara f’ ọkan mi.
English – It Is Well With My Soul
Verse 1
When peace like a river, attendeth my way,
When sorrows like sea billows roll;
Whatever my lot, Thou hast taught me to say
It is well, it is well, with my soul.
Chorus
It is well …. with my soul,
It is well, it is well, with my soul.
Verse 2
Though Satan should buffet, though trials should come,
Let this blest assurance control,
That Christ has regarded my helpless estate,
And hath shed His own blood for my soul.
Verse 3
And, Lord haste the day when the faith shall be sight,
The clouds be rolled back as a scroll,
The trump shall resound and the Lord shall descend,
`Even so` — it is well with my soul.