Yoruba Hymn: Mo yọ púpọ pe Jesu fẹ mi – I am so glad that Jesus loves me

Hymn: Mo yo pupo pe Baba wa orun – I am so glad that our Father in Heav’n
Bible Reference:
1 John 3:1 NKJV – Behold what manner of love the Father has bestowed on us, that we should be called children of God! Therefore the world does not know us, because it did not know Him.
1 Johannu 3:1 – Ẹ wo irú ifẹ ti Baba fi fẹ wa, ti a fi npè wa ni ọmọ Ọlọrun; bẹ̃ li a sa jẹ. Nitori eyi li aiye kò ṣe mọ̀ wa, nitoriti ko mọ̀ ọ.
Mo yo pipo pe Baba wa orun
Mo yọ púpọ pe Baba wa ọrún Sọ t'ifẹ Rẹ ninu 'we t'o fun mi, Mo r' ohun 'yanu ninu Bibeli, Eyi s'ọwọn ju pe Jesu fẹ mi, Chorus: Mo yọ púpọ pe Jesu fẹ mi, Jesu fẹ mi, Jesu fẹ mi, Mo yọ pupọ pe Jesu fẹ mi, Jesu fẹ an' emi.
Gba mo gbagbe Rẹ, ti emi sa lọ O fẹ mi sibẹ, O wa mi kiri, Mo yara pada s' apa anu Re, 'Gbati mo ranti pe Jesu fẹ mi.
Bi o ṣe orin kan l' emi le kọ, 'Gba mo r' Ọba nla ninu ewa Rẹ, Eyi ni yio ma j'orin mi titii, A! iyanu nip e Jesu fẹ mi.
Jesu fẹ mi, mo si mọ pe mo fẹ Ẹ, Ifẹ l'o mu wa r' okan mi pada, Ife lo m' U ko ku l' ori igi, O da mi loju pe Jesu fẹ mi.
Emi o ti ṣe dahun b' a bi mi Ohun ti Ogo Oluwa mi jẹ? Ẹmi Mímọ njẹri nin' ọkan mi, Ni igbagbo pe Jesu fẹ mi.
Ni gbẹkẹle yi mo r' isimi, Ni gbẹkẹle Krist, mo d' alabukun, Satan damu sa kuro l' ọkan mi, Nigba mo sọ fun pe Jesu fẹ mi.
I am so glad that our Father in Heav’n
I am so glad that our Father in Heav’n Tells of His love in the Book He has giv’n; Wonderful things in the Bible I see, This is the dearest, that Jesus loves me. Chorus I am so glad that Jesus loves me, Jesus loves me, Jesus loves me. I am so glad that Jesus loves me, Jesus loves even me.
Though I forget Him, and wander away, Still He doth love me wherever I stray; Back to His dear loving arms I do flee, When I remember that Jesus loves me.
Oh, if there’s only one song I can sing, When in His beauty I see the great King, This shall my song through eternity be, “Oh, what a wonder that Jesus loves me!”
Jesus loves me, and I know I love Him; Love brought Him down my poor soul to redeem; Yes, it was love made Him die on the tree; Oh, I am certain that Jesus loves me!
If one should ask of me, how can I tell? Glory to Jesus, I know very well! God’s Holy Spirit with mine doth agree, Constantly witnessing Jesus loves me.
In this assurance I find sweetest rest, Trusting in Jesus, I know I am blessed; Satan, dismayed, from my soul now doth flee, When I just tell him that Jesus loves me.