Yoruba Hymn: Jerusalem T’ọrun – Jerusalem on High
Hymn 963: Christ Apostolic Church Hymnal – Jerusalem T’ọrun
Bible Reference: But now they desire a better, that is, a heavenly country. Therefore God is not ashamed to be called their God, for He has prepared a city for them. Hebrews 11:16 NKJV
Ṣugbọn nisisiyi nwọn nfẹ ilu kan ti o dara jù bẹ̃ lọ, eyini ni ti ọ̀run: nitorina oju wọn kò ti Ọlọrun, pe ki a mã pe On ni Ọlọrun wọn; nitoriti o ti pèse ilu kan silẹ fun wọn. – Heberu 11:16
Jerusalem ‘t’ọrun
Jerusalem 't'ọrun L'orin mi, ilu mi Ile mi bi mbá ku; Ẹkùn ibukun mi; Ibi ayọ! Nigbawo ni Un o r'oju Rẹ Ọlọrun mi?
Níbẹ l'Ọba mi wa, T'ada l'ẹbi l'aye, Angẹli nkọrin fún Wọn sì ntẹriba fún
Patriark igbani, Par'ayọ wọn níbẹ Awọn woli, wọn nwọ, Ọmọ Aládé wọn
Níbẹ ni mo le ri Awọn Àpọsteli At'awọn akọrin Ti nlu harpu wura
Ni àgbàlá wọnni Ni awọn Martir wa; Wọn wọ asọ ala, Ogo bo ọgbẹ wọn
T'emi yi sa su mi, Ti mo ngb'ago kedar; Kò sí 'ru yi loke, Níbẹ ni mo fẹ lọ. Amin
Jerusalem on high
Jerusalem on high My song and city is, My home whene'er I die, The center of my bliss: Chorus: O happy place! When shall I be, My GOD, with Thee, To see Thy Face?
There dwells my Lord, my King, Judged here unfit to live; There Angels to Him sing, And lowly homage give:
The Patriarchs of old There from their travels cease; The Prophets there behold Their longed-for Prince of Peace:
The LAMB's Apostles there I might with joy behold; The harpers I might hear Harping on harps of gold;
The bleeding Martyrs, they Within those courts are found, Clothed in pure array, Their scars with glory crowned:
Ah! woe is me! that I In Kedar's tents here stay: No place like that on high; LORD, thither guide my way: