Yoruba Hymn: Halleluya, Ẹ gbe Ohun Ayọ Ga – Hallelujah! Hearts to Heaven

Halleluya, Ẹ gbe ohun ayọ ga – Hallelujah! Hearts to heaven
Bible Reference:
1 Peter 1:3- Blessed be the God and Father of our Lord Jesus Christ, which according to his abundant mercy hath begotten us again unto a lively hope by the resurrection of Jesus Christ from the dead
1 Peteru 01:3 – Olubukún li Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Ẹniti o tún wa bí, gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀, sinu ireti ãye nipa ajinde Jesu Kristi kuro ninu okú
Halleluya, Ẹ gbe ohun ayọ ga
Halleluya, Halleluya, Ẹ gbe ohun ayọ ga, Ẹ kọ orin inu didun, K’ẹ si yin Ọlọrun wa; Enit’a kan m’agbelebu, T’o jiya fun ẹsẹ wa; Jesu Kristi Ọba ogo Jinde kuro n’nu oku.
Irin idabu sẹ kuro, Kristi ku, O si tun ye, O mu iye ati aiku Wa l’orọ ajinde Rẹ; Kristi ti ṣẹgun, awa ṣẹgun Nipa agbara nla Rẹ, Awa o jinde pelu Re, A o ba wo’nu Ogo.
Kristi jinde, akọbi ni Ninu awọn t’o ti sun; Awon yi ni y’o ji dide, Ni abọ Rẹ ekeji; Ikore ti wọn ti pọn tan, Nwon nreti Olukore, Eniti y’o mu wọn kuro, Ninu isa oku wọn.
Awa jinde pẹlu Kristi, To nfun wa l’ohun gbogbo, Ojo, iri, ati ogo To ntan jade loju Rẹ, Oluwa, b’ a ti wa l’aiye, Fa ọkan wa sọdọ Rẹ, K’awọn angẹli sa wa jọ, Kin wọn ko wa d’ọdọ Rẹ.
Halleluya, Halleluya! Ogo ni fun Ọlọrun; Halleluya f’ Olugbala, Ẹnit’O ṣẹgun iku; Halleluya f’ Ẹmi Mimọ, Orisun ’fẹ, ’wa mimọ, Halleluya, Halleluya, F’Ọlọrun Mẹtalọkan. Amin
Hallelujah! Hearts to heaven
Hallelujah, Hallelujah! Hearts to heaven and voices raise: Sing to God a hymn of gladness, Sing to God a hymn of praise. He, who on the cross a victim, For the world's salvation bled, Jesus Christ, the King of glory, Now is risen from the dead.
Now the iron bars are broken, Christ from death to life is born, Glorious life, and life immortal, On this holy Easter morning. Christ has triumphed, and we conquer By his mighty enterprise: We with him to life eternal By his resurrection rise.
Christ is risen, Christ, the first fruits Of the holy harvest field, Which will all its full abundance At his second coming yield: Then the golden ears of harvest Will their heads before him wave, Ripened by his glorious sunshine From the furrows of the grave.
Christ is risen, we are risen! Shed upon us heavenly grace, Rain and dew and gleams of glory From the brightness of thy face; That we, with our hearts in heaven, Here on earth may fruitful be, And by angel hands be gathered, And be ever, Lord, with thee.
Hallelujah, Hallelujah! Glory be to God on high; Alleluia! to the Savior Who has gained the victory; Alleluia! to the Spirit, Fount of love and sanctity: Alleluia, alleluia! To the Triune Majesty. Amin.