Yoruba Hymn: A f’ọpẹ f’Ọlọrun – Now thank we all our God

Yoruba Hymn: A f’ọpẹ f’Ọlọrun – Now thank we all our God

CAC Hymn 89: A f’ọpẹ f’ỌlọrunNow thank we all our God

Bible Reference:

Psalms 48:14 NLT – For that is what God is like. He is our God forever and ever, and he will guide us until we die

Orin Dafidi 48:14 – Nitori Ọlọrun yi Ọlọrun wa ni lai ati lailai: on ni yio ma ṣe amọna wa titi ikú.

A f’ọpẹ f’Ọlọrun

Ẹsẹ 1
A f’ ọpẹ f’ Ọlọrun
L’ ọkan ati l’ ohun wa,
Ẹni ṣ’ ohun ‘yanu,
N’ nu Ẹnit’ araye nyọ;
Gbat’ a wá l’ ọm’ ọwọ
Oun na l’ o ntọju wa
O si nf’ ẹbun ifẹ
Ṣe ‘tọju wa sibẹ.

Ẹsẹ 2
Ọba Onib’ ọrẹ
Má fi wa silẹ lailai,
Ayọ ti kò lopin
Oun ‘bukun y’ o jẹ tiwa;
Pa wa mọ n’ nu ore,
Tọ wa gb’ a ba damu
Yọ wa ninu ibi
Laye ati l’ ọrun.

Ẹsẹ 3
K’ a f’ iyin oun ọpẹ
F’ Ọlọrun Baba, Ọmọ,
Ati Ẹmi Mimọ,
Ti o ga julọ l’ Ọrun,
Ọlọrun kan laelae,
T’aye at’ ọrun mbọ
Bẹẹ l’ o wà d’ isiyi,
Bẹẹni y’o wà laelae.

Now thank we all our God

Verse 1
Now thank we all our God,
With heart, and hands, and voices,
Who wondrous things hath done,
In whom His world rejoices;
Who from our mother’s arms
Hath bless’d us on our way
With countless gifts of love,
And still is ours today.

Verse 2
Oh may this bounteous God
Through all our life be near us,
With ever joyful hearts
And blessed peace to cheer us;
And keep us in His grace,
And guide us when perplex’d,
And free us from all ills,
In this world and the next.

Verse 3
All praise and thanks to God
The Father now be given,
The Son, and Holy Ghost,
Supreme in highest heaven,
The One eternal God,
Whom earth and heaven adore,
For thus it was, is now,
And shall be evermore.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *