Yoruba Hymn: Wá ẹnyin ọlọpẹ wa – Come, ye thankful people, come

Wá ẹnyin ọlọpẹ wa – Come, ye thankful people, come
Bible Reference:
Psalms 126:5 NLT – Those who plant in tears will harvest with shouts of joy.
ORIN DAFIDI 126:5 YCE – Àwọn tí ń fọ́n irúgbìn pẹlu omi lójú, jẹ́ kí wọn kórè rẹ̀ tayọ̀tayọ̀.
Ẹsẹ 1
Wá ẹnyin ọlọpẹ wa,
Gbe orin ìkórè ga
Ire gbogbo ti wọlé
Sori awọn araye,
Ọlọrun Ẹlẹda wa,
Jehofa Ọba Ogo,
Y’o ṣe idajọ aye,
‘Tori awọn Ayanfẹ.
Ẹsẹ 2
Oko Ọlọrun l’aye,
Lati s’eso iyin Rẹ;
Alikama at’epo
Ndagba f’àrò tab’ ayọ,
Ehu su, ipẹ tẹle
Ṣiri ọkà sí kẹhìn
Oluwa ‘kore mu wa
Jẹ eso rere fun Ọ.
Ẹsẹ 3
N’tori Ọlọrun wa mbọ,
Y’o si kore Rẹ sile,
Oun o gba gbogbo panti
Kuro l’oko Rẹ n’jọ nã:
Y’o f’aṣẹ f’awọn Angẹl’
Lati gba epo s’ina,
Lati ko alikama
Si aba Rẹ titi lae.
Ẹsẹ 4
Bẹẹni, maa bọ, Oluwa
Si ikore ikẹhin,
Ko awọn enia Rẹ jọ
Kuro nn’ẹṣẹ at’aro;
Sọ wọn di mimọ laelae,
Ki wọn le mã ba Ọ gbe,
Wa, t’ Iwọ t’ Angẹli Rẹ,
Gbe orin ìkórè ga.
ENGLISH
Verse 1
Come, ye thankful people, come,
Raise the song of harvest home:
All is safely gathered in,
Ere the winter storms begin;
God, our maker, doth provide
For our wants to be supplied:
Come to God’s own temple, come,
Raise the song of harvest home!
Verse 2
All the world is God’s own field,
Fruit unto His praise to yield;
Wheat and tares together sown,
Unto joy or sorrow grown;
First the blade and then the ear,
Then the full corn shall appear:
Lord of harvest grant that we
Wholesome grain and pure may be.
Verse 3
For the Lord our God shall come,
And shall take His harvest home;
From His field shall in that day
All offenses purge away;
Give His angels charge at last
In the fire the tares to cast;
But the fruitful ears to store
In His garner evermore.
Verse 4
Even so, Lord, quickly come;
To Thy final harvest home:
Gather Thou Thy people in,
Free from sorrow, free from sin;
There, for ever purified,
In Thy garner to abide:
Come, with all Thine angels, come,
Raise the glorious harvest-home!