Yoruba Hymn: Oluwa orun oun aye – O Lord of heaven and earth and sea

Yoruba Hymn: Oluwa orun oun aye – O Lord of heaven and earth and sea

CACHymn 662: Oluwa orun oun aye – O Lord of heaven and earth and sea

Bible Reference: 

1 Chronicles 29:14 NKJV – But who am I, and who are my people, That we should be able to offer so willingly as this? For all things come from You, And of Your own we have given You

1 Kronika 29:14 –  Ṣugbọn tali emi, ati kili awọn enia mi, ti a fi le ṣe iranlọwọ tinutinu bi iru eyi? nitori ohun gbogbo ọdọ rẹ ni ti wá, ati ninu ohun ọwọ rẹ li awa ti fi fun ọ

Oluwa orun oun aye

VERSE 1

Oluwa ọrun oun aye
'Wọ niyin at’ ọpẹ yẹ fun
Bawo la ba ti fẹ Ọ to
Onibu ọrẹ 

VERSE 2

Orun ti nran at’ afẹfẹ 
Gbogbo eweko nsọ fẹ Rẹ 
Wọ l’O nmu irugbin dara
Onibu ọrẹ 

VERSE 3

Fun ara lile wa gbogbo
Fun gbogbo ibukun aye
Awa yin Ọ, a si dupẹ 
Onibu ọrẹ 

VERSE 4

O ko du wa li Ọmọ Rẹ 
O fi fun aye ẹsẹ yi
Pẹlu Rẹ l'ọfẹ f'o nfun wa
L'ohun gbogbo

VERSE 5

O fun wa l’Ẹmi Mimọ Rẹ 
Emi iye at’agbara
O rọ’ jo ẹkun ibukun Rẹ 
Le wa lori

VERSE 6

Fun idariji ẹsẹ wa,
Ati fun ireti ọrun
Ki lohun ta fin fun Ọ
Onibu ọrẹ 

VERSE 7

Owo ti a nna, ofo ni
Ṣugbọn eyi ta fi fun Ọ 
O jẹ isura tit’ aye
Onibu ọrẹ 

VERSE 8

Ohun ta bun Ọ Oluwa
Wo O san le pada fun wa
Layọ la o ta Ọ lọrẹ 
Onibu ọrẹ 

VERSE 9

Ni odo Rẹ l’a ti san wa
Ọlọrun Olodumare
Jẹ ka le ba Ọ gbe titi
Onibu ọrẹ 

OH LORD OF HEAVEN AND EARTH AND SEA

VERSE 1

O Lord of heaven and earth and sea,
To Thee all praise and glory be;
How shall we show our love to Thee,
Giver of all!

VERSE 2

The golden sunshine, vernal air,
Sweet flowers and fruits, Thy love declare
Where harvests ripen, Thou art there,
Giver of all!

VERSE 3

For peaceful homes and healthful days,
For all the blessings earth displays,
We owe Thee thankfulness and praise,
Giver of all!

VERSE 4

Thou didst not spare Thine only Son,
But gav’st Him for a world undone,
And freely with that Blessed One,
Thou givest all!

VERSE 5

Thou giv’st the Holy Spirit’s dower,
Spirit of life, and love, and power,
And dost His sevenfold graces shower
Upon us all

VERSE 6

For souls redeemed, for sins forgiven,
For means of grace, and hopes of Heaven,
Father, what can to Thee be given,
Who givest all!

VERSE 7

We lose what on ourselves we spend:
We have as treasure without end
Whatever, Lord, to Thee we lend,
Who givest all!

VERSE 8

Whatever, Lord, we lend to Thee
Repaid a thousandfold will be,
Then gladly will we give to Thee
Giver of all!

VERSE 9

To Thee, from Whom we all derive
Our life, our gifts, our power to give,
Oh, may we ever with Thee live,
Giver of all!

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *