Yoruba Hymn: Nigbat’ idanwo yi mi ka – When temptation around me roll
Hymn: Nigbat’ idanwo yi mi ka – When temptation around me roll
Bible Reference: Genesis 3:9 (KJV) Where art thou?
Genesis 03:9b – Nibo ni iwọ wà?
Nigbat’ idanwo yi mi ka
Nigbat’ idanwo yi mi ka, Ti idamu aiye yi mi kai; T’ọta f’ ara han bi ọrẹ Lati wa iparun fun mi; Oluwa jo, ma s’aipe mi B’o ti pe Adam nin’ ogba Pe, “Nibo l’o wa” elese? Ki nle bọ ninu ẹbi na.
Nigbat’ Esu n’nu ’tanjẹ rẹ Gbe mi gori oke aiye, T’o ni ki ntẹriba fun on, K’ohun aiye le je temi. Oluwa jo, ma s’aipe mi B’o ti pe Adam nin’ ogba Pe, “Nibo l’o wa” elese? Ki nle bọ ninu ẹbi na.
’Gbat’ ogo aiye ba fe fi Tulasi mu mi rufin Rẹ; T’o duro gangan lẹhin mi; Ni ileri pe, “Ko si nkan.” Oluwa jo, ma s’aipe mi B’o ti pe Adam nin’ ogba Pe, “Nibo l’o wa” elese? Ki nle bọ ninu ẹbi na.
Nigbati igbẹkẹle mi Di t’ogun ati t’orisa; T’ogede di adura mi, Ti ọfọ di ajisa mi. Oluwa jo, ma s’aipe mi B’o ti pe Adam nin’ ogba Pe, “Nibo l’o wa” elese? Ki nle bọ ninu ẹbi na.
Nigbati mo fẹ lati rin L’ adamọ at’ ìfẹ ’nu mi, T’ọkan mi nse hilahilo, Ti nko gbona, ti nko tutu. Oluwa jo, ma s’aipe mi B’o ti pe Adam nin’ ogba Pe, “Nibo l’o wa” elese? Ki nle bọ ninu ẹbi na.
Nigba mo sọnu bi aja, L’ aigbọ ifere ọdẹ mọ; Ti nko nireti ipada, Ti mo npa fọ ninu ẹsẹ. Oluwa jo, ma s’aipe mi B’o ti pe Adam nin’ ogba Pe, “Nibo l’o wa” elese? Ki nle bọ ninu ẹbi na.
Nigbati ko s’ alabaro; Ti Olutunu si jina; T’ ibanuje, b’iji lile, Tẹ ori mi ba n’ ironu. Oluwa jo, ma s’aipe mi B’o ti pe Adam nin’ ogba Pe, “Nibo l’o wa” elese? Kin le bo ninu ebi na. Amin
When temptation around me roll
When temptation around me roll, And earthly care me encompass; When the foe appear as a friend; To seek after my destruction
O Saviour Lord, bid me to come
As Thou in Eden, Adam called
Where art thou sinner sound the voice?
That I may from the fault be free.
When Satan craft’ly me deceive Me to earthly pinnacle raise Me entreated, him to worship That earthly stock, I may possess
When earthly lusts me now ensnare Thy commands me all to ignore, Upon my wand’ring heart impressed In vain assurance “All is well”
When all my hope and confidence Not in living God now repose; Vain incantations now my trust’ And lusty spells my song at dawn
When in my self will, love to walk In the dictates of wand’ring heart, When I in my un-stable breast, In unstable state, me abide.
When all my bearing lost, not found, And the tracer’s call me ignore; When no redemption my hope be, And wallowest me in my sins.
When counselors from me doth flee; And comforters to me estrange When sorrow like the whirl-wind rage, My head in penitence to bow
O Saviour Lord, bid me to come
As Thou in Eden, Adam called
Where art thou sinner sound the voice?
That I may from the fault be free. Amen.