Yoruba Hymn: Nigba kan ni Betlehemu – Once In Royal David’s City

Yoruba Hymn: Nigba kan ni Betlehemu – Once In Royal David’s City

CAC Hymn 527: Nigba kan ni Betlehemu Ile kekere kan wa

Bible Reference: 

‭‭Matthew‬ ‭2:1a‬ ‭NKJV‬‬ – Now after Jesus was born in Bethlehem of Judea

‭‭Mat‬ ‭2:1‬ ‬‬ –  A si bí Jesu ni Betlehemu ti Judea,

Nigba kan ni Betlehemu

Nigba kan ni Betlehemu
Ile kekere kan wa
Nib'i'ya kan tẹ mọ'rẹ si
Lori ibujẹ ẹran
Maria n'iya ọmọ na
Jesu Kristi l'ọmọ na
O t'ọrun wa s'ode aye
On l'Ọlọrun Oluwa;
O f'ile ẹran se ile
'Bujẹ ẹran fun 'busun
Lọdọ awọn otosi
Ni Jesu gbe li aye
Ni gbogbo igba ewe Rẹ 
O ngbọran o si mb'ọla
O fẹran Osi ntẹriba 
Fun iya ti ntọjú Rẹ!
O yẹ ki gbogbo' ọmọde 
K'o ṣe olugbolọran bẹ
'Tori On jẹ awoṣe wa
A ma dagba bi awa
O kere ko le da nkan ṣe 
A ma sọkún bi awa
O si le ba wa daro
O le ba wa yọ pẹlú 
A o foju wa ri nikẹhin 
Ni agbara ifẹ rẹ;
Nitori ọmọ rere yi
Ni Oluwa wa l'ọrun
O ntọ awa ọmọ Rẹ
S'ọna ibiti On lọ
Ki ṣe ni ibujẹ ẹran
Nibiti malu njẹun 
L'awa o ri; ṣugbọn lọrùn 
Lọwọ ọtun 'Ọlọrun;
'Gba 'wọn 'mọ Rẹ b'irawọ
Ba wa n'nu aṣọ ala. Amin. 

Once In Royal David’s City

Once in royal Davids city,
Stood a lowly cattle shed,
Where a mother laid her Baby,
In a manger for His bed:
Mary was that mother mild,
Jesus Christ, her little Child.
He came down to earth from heaven,
Who is God and Lord of all,
And His shelter was a stable,
And His cradle was a stall:
With the poor, and mean, and lowly,
Lived on earth our Saviour holy.
For He is our childhood's pattern;
Day by day, like us, He grew;
He was little, weak, and helpless,
Tears and smiles, like us He knew;
And He cares when we are sad,
And he shares when we are glad.
And our eyes at last shall see Him,
Through His own redeeming love;
For that Child so dear and gentle,
Is our Lord in heaven above:
And He leads His children on,
To the place where He is gone

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *