Yoruba Hymn: Jesu ye titi aiye – Jesus lives
Jesu ye titi aiye – Jesus lives!
Bible Reference:
Revelation 1:18 NKJV – I am He who lives, and was dead, and behold, I am alive forevermore. Amen. And I have the keys of Hades and of Death.
Ifihan 1:18 – Emi li ẹniti o mbẹ lãye, ti o si ti kú; si kiyesi i, emi si mbẹ lãye si i titi lai, Amin; mo si ní kọkọrọ ikú ati ti ipo-oku.
Jesu ye titi aiye
Verse 1
Jesu ye; titi aiye
Eru iku ko ba ni mo;
Jesu ye; Nitorina
Isa oku ko n’ ipa mo.
Alleluya!
Verse 2
Jesu ye; lat’ oni lo,
Iku je ona si iye;
Eyi y’o je ’tunu wa,
’Gbat’ akoko iku ba de.
Alleluya!
Verse 3
Jesu ye; fun wa l’ o ku,
Nje Tire ni a o ma se;
A o f’ okan funfun sin,
A o f’ ogo f’ Olugbala.
Alleluya!
Verse 4
Jesu ye; eyi daju,
Iku at’ ipa okunkun
Ki y’o le ya ni kuro
Ninu ife nla ti Jesu.
Alleluya!
Verse 5
Jesu ye; gbogbo ’joba
L’ orun, li aiye, di Tire;
E je ki a ma tele,
Ki a le joba pelu Re.
Alleluyah! Amin.
Jesus lives! Thy terrors now
Jesus lives! Thy terrors now
Can no longer, death, appall us;
Jesus lives! by this we know
Thou, O Grave, canst not enthrall us.
Alleluia!
Jesus lives; henceforth is death
But the gate of life immortal;
This shall calm our trembling breath
When we pass its gloomy portal.
Alleluia!
- Jesus lives; for us he died;
Then, alone to Jesus living,
Pure in heart may we abide,
Glory to our Saviour giving.
Alleluia!
- Jesus lives; our hearts know well
Nought from us his love shall sever;
Life, nor death, nor powers of hell
Tear us from his keeping ever.
Alleluia!
- Jesus lives; to him the throne
Over all the world is given:
May we go where He has gone,
Rest and reign with Him in heaven.
Alleluia! Amin.