Yoruba Hymn: Gbogbo Aye Gbe Jesu Ga – All hail The Power of Jesus Name.
Gbogbo aye gbe Jesu ga
Hymn no.77 of the Christ Apostolic Church Yoruba Hymn Book
All hail The Power of Jesus Name Yoruba version
Bible Reference:
Ifihan 17:14b…nitori on ni Oluwa awọn oluwa, ati Ọba awọn ọba: awọn ti o si wà pẹlu rẹ̀, ti a pè, ti a yàn, ti nwọn si jẹ olõtọ yio si ṣẹgun pẹlu..
Revelation 17:14b NKJV…These will make war with the Lamb, and the Lamb will overcome them, for He is Lord of Lords and King of kings; and those who are with Him are called, chosen, and faithful.”
- Gbogbo aye, gbe Jesu ga,
Angẹl’, ẹ wolẹ fún,
Angẹl’, ẹ wolẹ fún;
Ẹ mu ade Ọba Rẹ wa,
Ṣe l’Ọba awọn Ọba.
- Ẹ ṣe l’Ọba ẹyin Martyr,
Ti npe ni pẹpẹ Rẹ,
Ti npe ni pẹpẹ Rẹ;
Gbe gbongbo igi, Jesu ga,
Ṣe l’Ọba awọn Ọba.
- Ẹyin iru ọmọ Israẹli’
Ti a ti rapada,
Ti a ti rapada;
Ẹ ki Ẹni t’o gba yín la,
Ṣe l’Ọba awọn Ọba.
- Gbogbo eniyan ẹlẹsẹ
Rántí ‘banujẹ yin,
Rántí ‘banujẹ yin;
Ẹ tẹ ‘kogun yín s; ẹsẹ Rẹ
Ṣe l’Ọba awọn Ọba.
- Ki gbogbo orilẹ èdè,
Nigbogbo agbaye,
Nigbogbo agbaye:
Ki wọn ki, “Kabiyesile”
Ṣe l’Ọba awọn Ọba.
- A ba le pel’awon t’ọrun
Lati ma juba Rẹ,
Lati ma juba Rẹ;
K’a bale jọ jumọ kọrin,
Ṣe l’Ọba awọn Ọba.
Amin
All hail The Power of Jesus Name.
- All hail the pow’r of Jesus’ name!
Let angels prostrate fall,
Let angels prostrate fall;
Bring forth the royal diadem,
And crown Him, crown Him,
crown Him, crown Him;
And crown Him Lord of all!
- Ye chosen seed of Israel’s race,
Ye ransomed from the fall,
Ye ransomed from the fall,
Hail Him who saves you by His grace,
- Sinners, whose love can ne’er forget
The wormwood and the gall,
The wormwood and the gall,
Go, spread your trophies at His feet,
- Let every kindred, every tribe,
On this terrestrial ball,
On this terrestrial ball,
To Him all majesty ascribe,
- O that with yonder sacred throng
We at His feet may fall,
We at His feet may fall!
We’ll join the everlasting song.