Yoruba Hymn: Emi o kokiki Rẹ Oluwa
CS Hymn 661: Emi o kokiki Rẹ, Oluwa
Bible Reference:
Psalms 30:1 NKJV – I will extol You, O Lord, for You have lifted me up, And have not let my foes rejoice over me.
Orin Dafidi 30:01 – Emi o kokiki rẹ, Oluwa; nitori iwọ li o gbé mi leke, ti iwọ kò si jẹ ki awọn ọta mi ki ó yọ̀ mi.
EMI o kokiki Rẹ Oluwa
1. EMI o kokiki Rẹ, Oluwa, Iwọ ni o da mi n'ide, Iwọ ni ko jẹ ki ọta yọ mi, Ogo ni f'orukọ Rẹ. Egbe: Iyin, Ọla, Ogo ni fun Ọ, Agbara ati ipa jẹ Tirẹ, Ẹgbẹrun ahọn ko to yin Ọ, A wolẹ, a juba Rẹ.
2. Oluwa mi, emi kigbe pe Ọ, Iwọ si mu mi lara da; O yọ ọkan mi ninu 'sa oku, O si pa mi mọ l'aye. Egbe: Iyin, Ọla, Ogo...
3. Kọrin s'Oluwa ẹyin Séráfù, K'ẹ si dupẹ n'iwa mimọ Rẹ, Ibinu Rẹ ki pẹ ju 'sẹju kan, Iye l'oju rere Rẹ. Egbe: Iyin, Ọla, Ogo…
4. Bi ẹkun tilẹ pẹ di alẹ kan, Sibẹ ayọ de l'Owurọ; Alafia si de ni ọsan gangan; Mo tun di ipo mi mu. Egbe: Iyin, Ọla, Ogo…
5. Nigba t'Oluwa pa oju rẹ mọ, Ẹnu ya mi mo si kigbe; A! Ki l'ere ẹjẹ mi, Oluwa, Gba mba koju s'isa oku? Egbe: Iyin, Ọla, Ogo...
6. Bayi l'Oluwa mi gbọ igbe mi, O si sọ kanu mi d'ijo; O bọ asọ ọfọ kuro l'ọrun mi, O f'amure ayọ di mi. Egbe: Iyin, Ọla, Ogo…
7. A! Ogo mi dide si ma kọrin Ma fi ayọ kọrin s'oke; Oluwa n ó fi ọpẹ fun Ọ, N ó si ma yin Ọ lailai. Egbe: Iyin, Ọla, Ogo… AMIN