Yoruba Hymn: Oniṣẹgun nla wa nihin – The Great Physician now is near

Oniṣẹgun nla wa nihin – The Great Physician now is near
Hymn no.406 of the Christ Apostolic Church Hymn Book
Bible reference:
Psalms 107:20 NKJV He sent His word and healed them, And delivered them from their destructions.
Orin Dafidi 107:20 O rán ọ̀rọ rẹ̀, o si mu wọn lara da, o si gbà wọn kuro ninu iparun wọn.
Oniṣẹgun nla wa nihin
Verse 1
Oniṣẹgun nla wa nihin,
Jesu abanidaro;
Ọrọ Rẹ mu ni l’ara da,
A gbọ ohùn ti Jésù
Iro didun l’orin Seraf
Orukọ didun li ahọn;
Orin to dun julọ ni:
Jesu, Jesu, Jesu.
Verse 2
A fi gbogbo’ẹsẹ rẹ ji Ọ,
A gbọ ohùn ti Jésù
Rin lọ s’ọrun l’alafia
Si ba Jesu dé adé.
Verse 3
Gbogb’ogo fun Krist’O jinde
Mo gbagbọ nisisiyi;
Mo f’Orukọ Olugbala
Mo fẹ Orukọ Jesu
Verse 4
Orukọ Rẹ l’ẹru mi lọ,
Kò sí orúkọ míràn,
B’ọkan mi ti nfẹ láti gbọ
Orúkọ Rẹ ‘yebiye
Verse 5
Arakunrin, ẹ ba mi yin
Ẹ yin orukọ Jesu;
Arabinrin, gb’ohun soke,
Ẹ yin orukọ Jesu
Verse 6
Ọmọdé at’agbalagba
T’o fẹ orukọ Jesu
Le gba pe ‘fẹ nisisiyi
Lati ṣiṣẹ fún Jesu.
Verse 7
Nigbat’a ba si dé ọrùn
Ti a ba sì rí Jésù;
A o kọ rin yi tẹ ifẹ ka,
Orin orukọ Jesu