Yoruba Hymn: A f’ọ́pẹ f’Ọlọrun, L’ọkan ati l’ohun wa
Yoruba Hymn Lyrics: A f’ọ́pẹ f’Ọlọrun, L’ọkan ati l’ohun wa. – Now thank we all our God, with heart and hands and voices
A f’ọ́pẹ f’Ọlọrun,
L’ọkan ati l’ohun wa.
Ẹni s’ohun ‘yanu,
N’nu ẹni t’araye nyọ;
‘Gba’a wa l’ọm’ọ́wọ
On na l’ntọju wa
O sí nf’ẹbun ìfẹ
Ṣe ‘tọju wa sibẹ.
Ọba Onibu-ọrẹ
Ma fi wa sílẹ laelae.
Ayọ tí kò l’opin
On ‘bukun y’o jẹ ti wa
Pa wa, mọ n’nu ọrẹ
Tọ wa, gb’a ba damu;
Yọ wa, ninu ibi
Láyé ati l’ọrun
K’a f’iyin on ọpẹ,
F:Ọlọrun, Baba, Ọmọ
Ati Ẹmi Mimọ;
Ti Ọ ga jùlọ lọrùn,
Ọlọrun kan laelae.
T’aye at’ọrun mbọ
Bẹ l’o wa d’isiyi
Bẹni y’o wa laelae. Àmín.
Now thank we all our God, with heart and hands and voices,
Who wondrous things have done, in Whom this world rejoices;
Who from our mothers’ arms has blessed us on our way
With countless gifts of love, and still is ours today.
Oh, may this bounteous God through all our life be near us,
With ever joyful hearts and blessed peace to cheer us;
And keep us in His grace, and guide us when perplexed;
And guard us through all ills in this world, till the next!
All praise and thanks to God the Father now be given,
The Son, and Him Who reigns with Them in highest Heaven—
The one eternal God, Whom earth and Heav’n adore;
For thus it was, is now, and shall be evermore.