Yoruba Hymn: Ọkàn mi, yin Ọba Ọrun – Praise, my soul, the King of heaven

Ọkàn mi, yin Ọba Ọrun – Praise, my soul, the King of heaven
Bible Reference:
Psalms 103:1-2 NKJV Bless the LORD, O my soul; And all that is within me, bless His holy name! 2. Bless the LORD, O my soul, And forget not all His benefits
Orin Daf 103:1-2 – [1] FI ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi, ati gbogbo ohun ti o wà ninu mi, fi ibukún fun orukọ rẹ̀ mimọ́. [2] Fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi, má si ṣe gbagbe gbogbo ore rẹ̀:
Ẹsẹ 1
Ọkàn mi, yin Ọba Ọrun
Mu ọrẹ wa s’ ọdọ Rẹ
‘Wọ t’ a wòsan t’ a dariji,
Tal’ a ba ha yìn bi Rẹ?
Yin Oluwa, yin Oluwa,
Yin Ọba ainipẹkun.
Ẹsẹ 2
Yìn fun anu t’ o ti fihàn
F’ awọn baba ‘nu ‘pọnju;
Yin I ọkanna ni titi,
O lọra lati binu;
Yin Oluwa, yin Oluwa,
Ologo n’ nu otitọ.
Ẹsẹ 3
Bi baba li O ntọju wa,
O si mọ ailera wa;
Jẹjẹ l’ O ngbe wa l’ apa Rẹ
O gbà wa lọwọ ọta;
Yin Oluwa, yin Oluwa,
Anu Rẹ yi aye ka.
Ẹsẹ 4
A ngbà bi ‘tànná eweko,
T’ afẹfẹ nfẹ to si nrọ;
‘Gbati a nwà ti a si nkú,
Ọlọrun wà bakanna;
Yin Oluwa, yin Oluwa,
Ọba alainipẹkun.
Ẹsẹ 5
Angẹl’ ẹ jumọ ba wa bọ,
Ẹnyin nri lojukoju;
Orùn, Oṣupa, ẹ wolẹ,
Ati gbogbo agbaye,
Ẹ ba wa yin, Ẹ ba wa yin,
Ọlọrun Olotitọ.
ENGLISH
Verse 1
Praise, my soul, the King of heaven
To His feet thy tribute bring;
Ransom’d, heal’d, restored, forgiven,
Who like thee His praise shall sing?
Praise Him, praise Him, Praise Him,
Praise him, Praise the everlasting King.
Verse 2
Praise Him for His grace and favor
To our fathers in distress;
Praise Him, still the same as ever,
Slow to chide, and swift to bless:
Praise Him, praise Him, Praise Him,
Praise him, Glorious in His faithfulness.
Verse 3
Father-like He tends and spares us;
Well our feeble frame He knows;
In His hands He gently bears us,
Rescues us from all our foes
Praise Him, praise Him, Praise Him,
Praise him, Widely as His mercy flows.
Verse 4
Just like grass, our lives be compared,
Which can faint when the wind blows
For a while we live and we die
But the Lord remains the same
Praise Him, praise Him, Praise Him,
Praise him, Praise the everlasting King.
Verse 5
Angels, help us to adore Him,
Ye behold Him face to face;
Sun and moon, bow down before Him;
Dwellers all in time and space.
Praise Him, praise Him, Praise Him,
Praise him, Praise with us the God of grace. Amen.