Yoruba Hymn: O fun mi l’edidi Gbese nla ti mo jẹ
Hymn 698 – CHRIST APOSTOLIC CHURCH HYMNAL
O fun mi l’edidi
Gbese nla ti mo jẹ
B’o ti fún mi, O sí rẹrin
Pe; máṣe gbagbe mi
O fun mi l’edidi
O san igbese na,
B’ o ti fún mi, O sí rẹrin
Wipe; ma rántí mi.
Un o p’edidi na mọ,
Bi ‘gbese tilẹ tan,
O nsọ ìfẹ Ẹni t’ o san
Igbese na fún mi.
Mo wo mo si rẹrin,
Mo tun wo, mo sọkún,
Ẹri ìfẹ Rẹ sí mi ni,
Ùn o tọju rẹ titi.
Ki tun s’edidi mọ,
Ṣugbọn ìrántí ni,
Pe gbogbo igbese mi ni
Emmanueli san. Amin